Bi ijapa se yỌ ikun gbẹndu
Aalo o aalo, ni igba laelae, igba kan nlo igba kan nbo igba
kan ko lo ile aye gbo. Alo mi da leri ijapa ati Yannibo iyawo rẹ. Lẹhin opolopo odun ti ijapa ati Yannibo
ko tii se abiyamo won lo si ile babalawo ti yio ba won da si. Babalawo yẹ won wo osi ni obẹ eto ni
oun o se fun Yannibo jẹ. Oni ki won sanwo eto ohun yio ja ewe
ati egbo ati gbogbo ohun ti o ma jẹ ki
Yannibo loyun ki osi bimo. Oni bi oba to ojo mẹta ki
ijapa wa, lati gbe ikoko obẹ naa lo si ile fun iyawo rẹ.
Ijapa de ni ojo kẹta osi
gbe ikoko obẹ na. Baba alawo kilo fun gidi gidi
wipe Yannibo lo gbodo da jẹ obẹ na,
lẹyin eyi ijapa le la ikoko. Ijapa kanju gbe ikoko, o nlo si
ile pẹlu ikoko obẹ. Okan ijapa ko kuro ni obẹ yi. O si wo, o to eti ẹ la.
Ode ikoko o tun bosi ona. Bi o ti nrin
lo nfi ẹsẹ ko to n duro to nto obẹ la. Laipẹ Ijapa ri wipe oun ti jẹ ikoko obẹ de ilaji lo ba kuku jẹ gbogbo ẹ tan. Ogbe ikoko leri o bo si ona ile
okan re sẹsẹ bale.
Kio to dele iku rẹ bẹrẹ si
fa wu. Igba ti Yannibo ri oko re, oni ta lẹ
beere o, ko s’oko mi nile o. Ijapa ni Yannibo emi ma ni. Yannibo ro pe oyi
l’onse oun o bu s’ẹrin oni bi o ba tan ara rẹ tan, ko wa iro mi pa. O jẹ tete
ma lo ile rẹ oko mi fẹrẹ de. Ijapa ko ẹyin si yannibo oni wo mi lati ẹyin ,
Yannibo ri wipe oko oun ni, ogba ikoko lori rẹ, O la
obẹ kekere to sẹku. Nigbati ose diẹ ara bẹrẹ sii ni
ijapa, iku rẹ tubo nga si. Iku iyawo rẹ naa nga. Ijapa ba pada lo si odo babalawo, ofi orin b’ẹnu oni :
Babalawo mo wa bẹbẹ ...alugbirin,
babalawo mo wa bẹbẹ.....alugbirin.
Ogun t’o se fun mi lẹẹkan.....alugbiirin,
gbongbo lo ko mii lẹsẹ....alugbinrin,
mo fo wo babẹ mo
mu kẹnu...alugbinrin,
mo bo ju wo kun o ri
gbẹndu....alugbinrin,
babalawo mo wa bẹbẹ.....alugbirin. .
Baba lawo ko si nile, oti lo re irin ajo. Odi ojo ti babalawo
ba ti ajo de ki ikun Ijapa to le fa diẹ.
Itan yi ko w ape k’ama se oju kokoro. Oju kokoro ko dara.
All these stories were formulated in the days long ago when it is claimed animals could speak just like humans. The attraction that we have for different animals enables these stories to refer to certain animals as cunning...tortoise. crafty...fox or seriously focused the ...dogs.
ReplyDeleteThese different assignations and claims makes people love the folklore.